Native Bible

Ezekiel 25:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nítorí náà, Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu.

Ezekiel 25:9 in English

Ezekiel 25:9 · Berean Standard Bible

therefore I will indeed expose the flank of Moab beginning with its frontier cities—Beth-jeshimoth, Baal-meon, and Kiriathaim—the glory of the land.

Context

7nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” 8“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,” 9nítorí náà, Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu. 10Èmi yóò fi Moabu pẹ̀lú àwọn ará Ammoni lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ammoni láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo. 11Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí Moabu lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.