Esekiẹli 23:43
Ezekiel 23:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ sá nípa panṣágà ṣíṣe, ‘Nísinsin yìí jẹ kí wọn lo o bí panṣágà, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’
Ezekiel 23:43 in English
Ezekiel 23:43 · Berean Standard Bible
Then I said of her who had grown old in adulteries: ‘Now let them use her as a prostitute, for that is all she is!’
Context
41Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà. 42“Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú àwọn ara Sabeani láti aginjù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dáradára sì wà ní orí wọn. 43Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ sá nípa panṣágà ṣíṣe, ‘Nísinsin yìí jẹ kí wọn lo o bí panṣágà, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’ 44Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá panṣágà sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Ohola àti Oholiba. 45Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé panṣágà ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.