Native Bible

Ezekiel 23:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni ìwọ pe ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ wá sí ìrántí, ní ti rírin orí ọmú rẹ láti ọwọ́ àwọn ará Ejibiti, fún ọmú ìgbà èwe rẹ.

Ezekiel 23:21 in English

Ezekiel 23:21 · Berean Standard Bible

So you revisited the indecency of your youth, when the Egyptians caressed your bosom and pressed your young breasts.

Context

19Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ panṣágà ní Ejibiti. 20Nítorí ó fẹ́ olùfẹ́ àwọn olùfẹ́ wọn ní àfẹ́jù, tí àwọn tí nǹkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtújáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin. 21Báyìí ni ìwọ pe ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ wá sí ìrántí, ní ti rírin orí ọmú rẹ láti ọwọ́ àwọn ará Ejibiti, fún ọmú ìgbà èwe rẹ. 22“Nítorí náà, Oholiba, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojúkọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà 23àwọn ará Babeli àti gbogbo ara Kaldea àwọn ọkùnrin Pekodi àti Ṣoa àti Koa àti gbogbo ará Asiria pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.