Esekiẹli 23:11
Ezekiel 23:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.
Ezekiel 23:11 in English
Ezekiel 23:11 · Berean Standard Bible
Her sister Oholibah saw this, yet in her lust and prostitution she was more depraved than her sister.
Context
9“Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i. 10Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pa wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrín àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́. 11“Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. 12Òun náà ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ará Asiria àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà. 13Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.