Native Bible

Ezekiel 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

Ezekiel 22:5 in English

Ezekiel 22:5 · Berean Standard Bible

Those near and far will mock you, O infamous city, full of turmoil.

Context

3Kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère. 4Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú. 5Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá. 6“ ‘Wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀. 7Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.