Native Bible

Ezekiel 22:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

Ezekiel 22:29 in English

Ezekiel 22:29 · Berean Standard Bible

The people of the land have practiced extortion and committed robbery. They have oppressed the poor and needy and have exploited the foreign resident without justice.

Context

27Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. 28Àti àwọn wòlíì rẹ́ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì ìran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀ṣẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí,’ nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀. 29Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo. 30“Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. 31Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.