Native Bible

Ezekiel 22:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn.

Ezekiel 22:2 in English

Ezekiel 22:2 · Berean Standard Bible

“As for you, son of man, will you judge her? Will you pass judgment on the city of bloodshed? Then confront her with all her abominations

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn. 3Kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère. 4Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.