Native Bible

Ezekiel 22:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín.

Ezekiel 22:13 in English

Ezekiel 22:13 · Berean Standard Bible

Now look, I strike My hands together against your unjust gain and against the blood you have shed in your midst.

Context

11Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀. 12Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí. 13“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. 14Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. 15Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.