Esekiẹli 21:22
Ezekiel 21:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
Ezekiel 21:22 in English
Ezekiel 21:22 · Berean Standard Bible
In his right hand appears the portent for Jerusalem, where he is to set up battering rams, to call for the slaughter, to lift a battle cry, to direct the battering rams against the gates, to build a ramp, and to erect a siege wall.
Context
20La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi. 21Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ. Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀. 22Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́. 23Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn. 24“Nítorí náà èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.