Esekiẹli 21:2
Ezekiel 21:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli.
Ezekiel 21:2 in English
Ezekiel 21:2 · Berean Standard Bible
“Son of man, set your face against Jerusalem and preach against the sanctuaries. Prophesy against the land of Israel
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá: 2“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. 3Kí ó sì sọ fún un pe, ‘Èyí yìí ni Olúwa wí, Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. 4Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.