Esekiẹli 20:41
Ezekiel 20:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
Ezekiel 20:41 in English
Ezekiel 20:41 · Berean Standard Bible
When I bring you from the peoples and gather you from the lands to which you have been scattered, I will accept you as a pleasing aroma. And I will show My holiness through you in the sight of the nations.
Context
39“ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Israẹli, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́. 40Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín. 41Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. 42Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Israẹli; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín. 43Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.