Esekiẹli 20:31
Ezekiel 20:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, ìrúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú ọmọ yin la iná kọjá, ẹ̀yin ń tẹ̀síwájú láti ba ara yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, ẹ̀yin yóò ha jẹ wádìí lọ́dọ̀ mi, ìwọ ilé Israẹli? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi ki yóò jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.
Ezekiel 20:31 in English
Ezekiel 20:31 · Berean Standard Bible
When you offer your gifts, sacrificing your sons in the fire,* you continue to defile yourselves with all your idols to this day. So should I be consulted by you, O house of Israel? As surely as I live, declares the Lord GOD, I will not be consulted by you!
Context
29Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, kí ní ibi gíga tí ẹ̀yin lọ yìí?’ ” (Orúkọ rẹ̀ ni a sì ń pè ní Bama di òní yìí.) 30“Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, ṣé o fẹ́ ba ara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, tiwọn ń ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra? 31Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, ìrúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú ọmọ yin la iná kọjá, ẹ̀yin ń tẹ̀síwájú láti ba ara yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, ẹ̀yin yóò ha jẹ wádìí lọ́dọ̀ mi, ìwọ ilé Israẹli? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi ki yóò jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi. 32“ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ́ dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá. 33Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò jẹ ọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.