Native Bible

Ezekiel 20:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn.

Ezekiel 20:24 in English

Ezekiel 20:24 · Berean Standard Bible

For they did not practice My ordinances, but they rejected My statutes and profaned My Sabbaths, fixing their eyes on the idols of their fathers.

Context

22Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn. 23Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo, 24nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn. 25Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀; 26mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn nípa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun, àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí èmi sọ wọ́n di ahoro, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.