Esekiẹli 2:7
Ezekiel 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
Ezekiel 2:7 in English
Ezekiel 2:7 · Berean Standard Bible
But speak My words to them, whether they listen or refuse to listen, for they are rebellious.
Context
5Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀ nítorí pé wọ́n ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn. 6Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n. 7Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. 8Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.” 9Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.