Esekiẹli 17:20
Ezekiel 17:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi.
Ezekiel 17:20 in English
Ezekiel 17:20 · Berean Standard Bible
I will spread My net over him and catch him in My snare. I will bring him to Babylon and execute judgment upon him there for the treason he committed against Me.
Context
18Nítorí pé ó kẹ́gàn ìbúra nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kì yóò bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣe yìí. 19“ ‘Nítorí náà Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ti wà láààyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀. 20Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi. 21Gbogbo ìgbèkùn àti ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.” 22“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.