Esekiẹli 16:7
Ezekiel 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora.
Ezekiel 16:7 in English
Ezekiel 16:7 · Berean Standard Bible
I made you thrive like a plant of the field. You grew up and matured and became very beautiful. Your breasts were formed and your hair grew, but you were naked and bare.
Context
5Kò sí ẹni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ dé bi à ti ṣe nǹkan kan nínú ìwọ̀nyí fún ọ, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ. 6“ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!” Nítòótọ́, nígbà tí ìwọ wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, “Yè.” 7Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora. 8“ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni Olúwa Olódùmarè wí. 9“ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ara rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.