Native Bible

Ezekiel 16:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Nítorí pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé, Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sí orí rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí, ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ mọ́?

Ezekiel 16:43 in English

Ezekiel 16:43 · Berean Standard Bible

Because you did not remember the days of your youth, but enraged Me with all these things, I will surely bring your deeds down upon your own head, declares the Lord GOD. Have you not committed this lewdness on top of all your other abominations?

Context

41Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́. 42Nígbà náà ni ìbínú mi sí o yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ̀, èmi kò sì ní bínú mọ́.” 43“ ‘Nítorí pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé, Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sí orí rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí, ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ mọ́? 44“ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.” 45Ìwọ ni ọmọ ìyá rẹ ti ó kọ ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀; ìwọ ni arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ tí ó kọ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn: ara Hiti ni ìyá rẹ, ara Amori sì ni baba rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.