Native Bible

Ezekiel 14:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ ronúpìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín, kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!

Ezekiel 14:6 in English

Ezekiel 14:6 · Berean Standard Bible

Therefore tell the house of Israel that this is what the Lord GOD says: ‘Repent and turn away from your idols; turn your faces away from all your abominations.

Context

4Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tó gbé òrìṣà sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, tí ó sì wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni yóò dá ẹni tí ó wa lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ. 5Èmi yóò ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Israẹli tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’ 6“Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ ronúpìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín, kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀! 7“ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Israẹli, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní èmi yóò dá a lóhùn. 8Èmi yóò lòdì si irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, Èmi yóò sì fi i ṣe àmì àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.