Esekiẹli 14:23
Ezekiel 14:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi kò ṣe nǹkan kan láìnídìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.”
Ezekiel 14:23 in English
Ezekiel 14:23 · Berean Standard Bible
They will bring you consolation when you see their conduct and actions, and you will know that it was not without cause that I have done all these things within it,’ declares the Lord GOD.”
Context
21“Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jerusalẹmu, èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-ààrùn láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀! 22Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ̀yin yóò rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jerusalẹmu—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀. 23Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi kò ṣe nǹkan kan láìnídìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.