Native Bible

Ezekiel 14:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ilé Israẹli má ba à ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ, kí wọ́n má ba à fi gbogbo ìrékọjá ba ara wọn jẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ezekiel 14:11 in English

Ezekiel 14:11 · Berean Standard Bible

in order that the house of Israel may no longer stray from Me and no longer defile themselves with all their transgressions. Then they will be My people and I will be their God, declares the Lord GOD.’”

Context

9“ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi Israẹli. 10Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀. 11Kí ilé Israẹli má ba à ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ, kí wọ́n má ba à fi gbogbo ìrékọjá ba ara wọn jẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 12Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 13“Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, èmi yóò rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.