Esekiẹli 13:18
Ezekiel 13:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálùkù ènìyàn láti ṣọdẹ ọkàn wọn. Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi bí? Ẹ̀yin yóò sì gba ọkàn ti ó tọ̀ yín wá là bí?
Ezekiel 13:18 in English
Ezekiel 13:18 · Berean Standard Bible
and tell them that this is what the Lord GOD says: Woe to the women who sew magic charms on their wrists and make veils for the heads of people of every height, in order to ensnare their souls. Will you ensnare the souls of My people but preserve your own?
Context
16Àwọn wòlíì Israẹli tí ń sọtẹ́lẹ̀ sí Jerusalẹmu, tí wọn ríran àlàáfíà sí i nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí.” ’ 17“Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn 18wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálùkù ènìyàn láti ṣọdẹ ọkàn wọn. Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi bí? Ẹ̀yin yóò sì gba ọkàn ti ó tọ̀ yín wá là bí? 19Nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà barle àti òkèlè oúnjẹ. Ẹ ti pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì fi àwọn tí kò yẹ kó wà láààyè sílẹ̀ nípa irọ́ tí ẹ ń pa fún àwọn ènìyàn mi, èyí tí àwọn náà ń fetí sí. 20“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín, Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.