Esekiẹli 13:12
Ezekiel 13:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn kò níbi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”
Ezekiel 13:12 in English
Ezekiel 13:12 · Berean Standard Bible
Surely when the wall has fallen, you will not be asked, ‘Where is the whitewash with which you covered it?’
Context
10“ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà,” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún, 11nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, Èmi yóò sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀. 12Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn kò níbi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?” 13“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lé e lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi láti pa wọ́n run. 14Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ dé bi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.