Esekiẹli 12:19
Ezekiel 12:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé, pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.
Ezekiel 12:19 in English
Ezekiel 12:19 · Berean Standard Bible
Then tell the people of the land that this is what the Lord GOD says about those living in Jerusalem and in the land of Israel: ‘They will eat their bread with anxiety and drink their water in dread, for their land will be stripped of everything in it because of the violence of all who dwell in it.
Context
17Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18“Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà. 19Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé, pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀. 20Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ” 21Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.