Native Bible

Ezekiel 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

Ezekiel 12:1 in English

Ezekiel 12:1 · Berean Standard Bible

Then the word of the LORD came to me, saying,

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n. 3“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.