Esekiẹli 1:20
Ezekiel 1:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn.
Ezekiel 1:20 in English
Ezekiel 1:20 · Berean Standard Bible
Wherever the spirit would go, they would go, and the wheels would rise alongside them, because the spirit of the living creatures was in the wheels.
Context
18Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká. 19Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. 20Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. 21Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́. 22Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.