Native Bible

Ezekiel 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀.

Ezekiel 1:13 in English

Ezekiel 1:13 · Berean Standard Bible

In the midst of the living creatures was the appearance of glowing coals of fire, or of torches. Fire moved back and forth between the living creatures; it was bright, and lightning flashed out of it.

Context

11Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn. 12Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ. 13Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀. 14Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá. 15Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.