Native Bible

Exodus 9:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.

Exodus 9:7 in English

Exodus 9:7 · Berean Standard Bible

Pharaoh sent officials and found that none of the livestock of the Israelites had died. But Pharaoh’s heart was hardened,* and he would not let the people go.

Context

5Olúwa sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.” 6Olúwa sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ará Ejibiti kú, ṣùgbọ́n ẹyọ kan kò kú lára ẹran ọ̀sìn àwọn Israẹli. 7Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ. 8Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao. 9Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.