Eksodu 9:29
Exodus 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.
Exodus 9:29 in English
Exodus 9:29 · Berean Standard Bible
Moses said to him, “When I have left the city, I will spread out my hands to the LORD. The thunder will cease, and there will be no more hail, so that you may know that the earth is the LORD’s.
Context
27Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo. 28Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.” 29Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀. 30Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.” 31(A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.