Eksodu 9:25
Exodus 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.
Exodus 9:25 in English
Exodus 9:25 · Berean Standard Bible
Throughout the land of Egypt, the hail struck down everything in the field, both man and beast; it beat down every plant of the field and stripped every tree.
Context
23Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti. 24Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè. 25Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú. 26Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé. 27Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.