Native Bible

Exodus 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.

Exodus 9:10 in English

Exodus 9:10 · Berean Standard Bible

So they took soot from the furnace and stood before Pharaoh. Moses tossed it into the air, and festering boils broke out on man and beast.

Context

8Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao. 9Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” 10Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran. 11Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti. 12Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.