Native Bible

Exodus 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn tí Mose àti Aaroni tí kúrò ní iwájú Farao, Mose gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti rán sí Farao.

Exodus 8:12 in English

Exodus 8:12 · Berean Standard Bible

After Moses and Aaron had left Pharaoh, Moses cried out to the LORD for help with the frogs that He had brought against Pharaoh.

Context

10Farao wí pé, “Ni ọ̀la.” Mose sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa. 11Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò fi ìwọ àti àwọn ilé yín àti ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, wọn yóò sì wà nínú Naili nìkan.” 12Lẹ́yìn tí Mose àti Aaroni tí kúrò ní iwájú Farao, Mose gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti rán sí Farao. 13Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko. 14Wọ́n sì kó wọn jọ ni òkìtì òkìtì gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.