Eksodu 7:9
Exodus 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.”
Exodus 7:9 in English
Exodus 7:9 · Berean Standard Bible
“When Pharaoh tells you, ‘Perform a miracle,’ you are to say to Aaron, ‘Take your staff and throw it down before Pharaoh,’ and it will become a serpent.*”
Context
7Mose jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún Aaroni sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ni ìgbà tí wọ́n bá Farao sọ̀rọ̀. 8Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, 9“Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.” 10Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. 11Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.