Native Bible

Exodus 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Ejibiti,

Exodus 7:3 in English

Exodus 7:3 · Berean Standard Bible

But I will harden Pharaoh’s heart, and though I will multiply My signs and wonders in the land of Egypt,

Context

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ agbẹnusọ rẹ. 2Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀. 3Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Ejibiti, 4síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. 5Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.