Native Bible

Exodus 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”

Exodus 5:2 in English

Exodus 5:2 · Berean Standard Bible

But Pharaoh replied, “Who is the LORD that I should obey His voice and let Israel go? I do not know the LORD, and I will not let Israel go.”

Context

1Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ” 2Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.” 3Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.” 4Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.