Native Bible

Exodus 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti ṣe fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.”

Exodus 5:13 in English

Exodus 5:13 · Berean Standard Bible

The taskmasters kept pressing them, saying, “Fulfill your quota each day, just as you did when straw was provided.”

Context

11Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ” 12Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Ejibiti láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì. 13Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti ṣe fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.” 14Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?” 15Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Israẹli tọ Farao lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.