Eksodu 5:10
Exodus 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Farao sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.
Exodus 5:10 in English
Exodus 5:10 · Berean Standard Bible
So the taskmasters and foremen of the people went out and said to them, “This is what Pharaoh says: ‘I am no longer giving you straw.
Context
8Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’ 9Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.” 10Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Farao sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́. 11Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ” 12Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Ejibiti láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.