Eksodu 40:9
Exodus 40:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.
Exodus 40:9 in English
Exodus 40:9 · Berean Standard Bible
Take the anointing oil and anoint the tabernacle and everything in it; consecrate it along with all its furnishings, and it shall be holy.
Context
7gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀. 8Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà. 9“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́. 10Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. 11Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.