Native Bible

Exodus 40:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì.

Exodus 40:17 in English

Exodus 40:17 · Berean Standard Bible

So the tabernacle was set up on the first day of the first month of the second year.

Context

15Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.” 16Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. 17Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì. 18Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró. 19Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.