Native Bible

Exodus 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́.

Exodus 4:8 in English

Exodus 4:8 · Berean Standard Bible

And the LORD said, “If they refuse to believe you or heed the witness of the first sign, they may believe that of the second.

Context

6Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. 7Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù. 8Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́. 9Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.” 10Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.