Eksodu 39:32
Exodus 39:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Exodus 39:32 in English
Exodus 39:32 · Berean Standard Bible
So all the work for the tabernacle, the Tent of Meeting, was completed. The Israelites did everything just as the LORD had commanded Moses.
Context
30Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì:
Mímọ́ sí Olúwa. 31Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 32Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 33Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá:
àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; 34ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji aṣọ títa;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.