Native Bible

Exodus 39:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya.

Exodus 39:23 in English

Exodus 39:23 · Berean Standard Bible

with an opening in the center of the robe like that of a garment,* with a collar around the opening so that it would not tear.

Context

21Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 22Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun, 23pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya. 24Ó sì ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká. 25Ó sì ṣe agogo kìkì wúrà, ó sì so wọ́n mọ́ àyíká ìṣẹ́tí àárín pomegiranate náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.