Native Bible

Exodus 37:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Igi kasia ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà.

Exodus 37:25 in English

Exodus 37:25 · Berean Standard Bible

He made the altar of incense out of acacia wood. It was square, a cubit long, a cubit wide, and two cubits high.* Its horns were of one piece.

Context

23Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni. 24Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara tálẹ́ǹtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà. 25Igi kasia ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà. 26Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká. 27Ó ṣe òrùka wúrà méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní òdìkejì ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.