Native Bible

Exodus 37:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀.

Exodus 37:21 in English

Exodus 37:21 · Berean Standard Bible

A bud was under the first pair of branches that extended from the lampstand, a bud under the second pair, and a bud under the third pair.

Context

19Àwo mẹ́ta ni a ṣe bí ìtànná almondi pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà. 20Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 21Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 22Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. 23Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.