Native Bible

Exodus 37:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà.

Exodus 37:14 in English

Exodus 37:14 · Berean Standard Bible

The rings were placed close to the rim, to serve as holders for the poles used to carry the table.

Context

12Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 13Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 14Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. 15Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 16Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.