Eksodu 36:2
Exodus 36:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà.
Exodus 36:2 in English
Exodus 36:2 · Berean Standard Bible
Then Moses summoned Bezalel, Oholiab, and every skilled person whom the LORD had gifted—everyone whose heart stirred him to come and do the work.
Context
1Besaleli, Oholiabu àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti òye láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.” 2Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà. 3Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀. 4Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́-ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.