Eksodu 36:11
Exodus 36:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì.
Exodus 36:11 in English
Exodus 36:11 · Berean Standard Bible
He made loops of blue material on the edge of the end curtain in the first set, and also on the end curtain in the second set.
Context
9Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. 10Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. 11Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. 12Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. 13Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.