Native Bible

Exodus 35:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda,

Exodus 35:30 in English

Exodus 35:30 · Berean Standard Bible

Then Moses said to the Israelites, “See, the LORD has called by name Bezalel son of Uri, the son of Hur, of the tribe of Judah.

Context

28Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. 29Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose. 30Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31Ó sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 32Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.