Eksodu 34:8
Exodus 34:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn.
Exodus 34:8 in English
Exodus 34:8 · Berean Standard Bible
Moses immediately bowed down to the ground and worshiped.
Context
6Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, 7Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.” 8Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn. 9Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.” 10Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ Èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí Èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.