Eksodu 34:22
Exodus 34:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso alikama àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún.
Exodus 34:22 in English
Exodus 34:22 · Berean Standard Bible
And you are to celebrate the Feast of Weeks * with the firstfruits of the wheat harvest, and the Feast of Ingathering * at the turn of the year.
Context
20Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà.
“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo. 21“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi. 22“Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso alikama àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún. 23Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa Olódùmarè, Ọlọ́run Israẹli. 24Èmi yóò lé orílẹ̀-èdè jáde níwájú rẹ, Èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.