Native Bible

Exodus 33:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.”

Exodus 33:20 in English

Exodus 33:20 · Berean Standard Bible

But He added, “You cannot see My face, for no one can see Me and live.”

Context

18Mose sì wí pé, “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.” 19Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí Èmi yóò ṣàánú fún, Èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí Èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún. 20Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.” 21Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta. 22Nígbà tí ògo mi bá kọjá, Èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, Èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí Èmi yóò fi rékọjá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.